Ètò àpérò ọlọ́jọ́ mẹ́ta lórí àwọn ǹnkan tí yóò máà jáde lórí afẹ́fẹ́ nílesẹ́ Radio Nigeria ìbàdàn ti kásẹ̀ nílẹ̀ ní Ìlárá Mọ̀kín, nípinlẹ̀ Òndó.

Àwọn olùkópa láwọn ẹ̀ka ilé-isẹ́ náà, yíká ẹkùn gúsù ìwọ̀orùn ilẹ̀ yíì, ló péjú pésẹ̀ síbẹ̀.

Nínú ìdánilẹ́kọ kan tó gbékalẹ̀ èyí tíwọ́n pe àkòrí rẹ̀ ni, mímú àgbéga bá Radio Nigeria gẹ́gẹ́ bí irinsẹ́ pàtàkì fún ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ní sáà tawàyí, olúdarí àgbà tẹ́lẹ̀ fúnlesẹ́ Radio Nigeria lẹ́kùn ìbàbàn, ọmọọba Atilade Atoyebi sọ pé, àwọn irinsẹ́ ìgbàlodé fún sẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ se pàtàkì fáwọn ǹnkan tí yóò bá máà lè bá jáfáfá si.

Ó tọ́kasi pé, ó se pàtàkì láti sàgbéyẹ̀wò àwọn ipò tírinsẹ́ wà, kíwọ́n sìridájú pé wọ́n ra àwọn irinsẹ́ tó bá tòde mu, pẹ̀lú àlàyé pé, ìgbésẹ̀ náà yóò mu ki àjọsepọ̀ tó dánmọ́rán wà laarin àwọn èèyàn nílesẹ́ ọ̀hún.

Ọmọọba Atoyebi wá sàpèjúwe ìgbésẹ̀ mímú àgbéga bá Radio gẹ́gẹ́ bí irinsẹ́ pàtàkì, le wa sí ìmúsẹ báwọn tọ́rọ̀ kan lẹ́ka ilé-isẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ gbọdọ̀ fọwọ́sowọ́pọ̀ kíwọ́n sì ní àjọsepọ̀ tó dánmọ́rán láarin arawọn àtàwọn alásẹ tọ́rọkàn.

Nígbà tó n sàgbéyẹ̀wò ìwé àpilẹ̀kọ kan, olùkọ́ kan nílé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Adekunle Ajasin, Akungba Akoko nípinlẹ̀ Òndó, ọ̀mọ̀wé Adedayọ Afẹ, tẹnumọ́ ìdí tó fi sepàtàkì fáwọn oníròyìn kíwọ́n jẹ́ akọ́sẹ́mọsẹ́ nídi isẹ́ ìròyìn, káwọn tọ́rọ̀ kan náà si máà se, ohun tó dára fún wọn.

Folakemi Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *