Ó se pàtàkì fún ìjọba òbí àta alágbàtọ́ láti máà fi ìwà ọmọlúàbí se àtìlẹyìn fáwọn ọmọ wọn

Níwọ̀nba ìgbà tó jẹ́ wípé gbogbo èèyàn ló gbà pe, ọmọdé lóni ni yóò di àgbà lọ́la, àtipé ọ̀dọ́ òní ni asíwájú lẹ́yìnwá ọ̀la, ó se pàtàkì fún ìjọba, òbí àta alágbàtọ́ láti máà fi gbogbo ǹkan tí wọ́n bá se àtìlẹyìn fáwọn ọmọ wọn, paapaa ìwà ọmọlúàbí àti ìwà bí Ọlọ́run lọ́nà àti gbawọn láradì sílẹ̀ de ọjọ iwájú wọn.

Alábojútó àgbà fún ìjọ The True Apostolic Church, Dógó, Àpáta, nílu Ìbàdàn, òjísẹ́ Ọlọ́run Israel Adebakin, ló gbé ọ̀rọ̀ ìmọ̀ràn yíì kalẹ̀ níbi àjọ̀dún ọdọọdún ìjọ náà, nígbà tó ńsọ èrò ọkàn rẹ̀ nípa àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Nàijírìa méjìdínlọ́gọ́rin táwọn òsìsẹ́ alábo ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ nílẹ̀ Amẹrica, FBI, mú lórí ẹ̀sùn ìwà jíbítí lójú òpó ẹ̀rọ ayélujára.

Ojíse Ọlọ́run Adebakin tó sọ̀rọ̀ lórí àkòrí “ Ọkàn Tuntun” kọminú lórí bí ìwà ìbàjẹ́ se ńfojoojúmọ́ pọ̀ si láàrin àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀èdè yíì àti ọ̀rọ̀ ètò àabò ti ìpèníjà lọ́kan ò jọ̀kan ‘ńbá fínra láwùjọ ilẹ̀ yí.

Nínú ọ̀rọ̀ tí ọ̀dọ́ kan níbi ètò náà, ọ̀gbẹ́ni Adenuga, ó di ẹ̀bi bí ìwà ìbàjẹ́ se ńdi tọ́rọ́fọ́nkálé láàrin àwọn ọ̀dọ́ ìwòyí rù, bí ìjọba se ńkùnà nínú ojúse rẹ̀ láti pèsè isẹ́ àti àyíká tó rọrùn fáwọn ọ̀dọ́ láti ma nkan musẹ.

Ọkan lára àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ elétò ìpàdé ọlọ́dọọdún náà, arábìnrin Motunrayọ Ojolumade, gba àdúra pé kí Ọlọ́run fọwọ́ tọ́ ọkàn àwọn tó wà nídi ètò àkóso ilẹ̀yí, kí wọ́n se ètò tó lè mú ìgbé ayé ìrọ̀rùn bá àwọn èèyàn orílẹ̀èdè yíì.

Lára ohun tó wáyé níbi ètò náà, àkànse àdúrà fún àlàafìa, ìsọ̀kan àti ìdúrósinsin orílẹ̀èdè Nàijírìa.

Babatunde Tiamiyu

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *