Àjọ tón mójútó isẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ nílẹ̀ yi, NBC, ti sọ pé ilésẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tó bá tàpá sófin ìlànà tó wà fun ni yo jìyà tótọ́ lábẹ́ òfin.

Olùdarí àgbà fájọ NBC, Àlhájì Modibbo Kawu ló sọ̀rọ̀ yi nílu Abuja, lásìkò ìdánilẹ́kọ ẹlẹ́kẹrin irú rẹ̀, tóma ń wáyé lọ́dọdún, tí wọn pe àkòrì rẹ̀ ní “ Àwọn Ìpèníjà tón kojú ilẹ̀ Nàijírìa: ìdí pàtàkì tó fi yẹ kísẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ gbilẹ̀”.

Ó ní isẹ́ tó wà níwájú àjọ ọ̀hún ló ti pọ̀si papa bí isẹ́ ìgbóhùnsẹ́fẹ́fẹ́ nílẹ̀yí yo ba máà táà kàngbọ̀n pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ lágbayé.

Alákoso fọ́rọ̀ ìròyìn àti àsà Àlhájì Lai Muhammed, ẹni tí ọ̀gágba fún ọ̀rọ̀ tóníse pẹ̀lú arálu Priscilla Ihuma sojúfún, sọ pé wọn yo sisẹ́ wọn dójúàmì láti mú àgbéga bá ẹ̀ka isẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́.

Àlhájì Muhammed wá rọ àwọn akọ̀ròyìn láti sa ipa wọn fi mú kálafia àti ìbásepọ̀ wà lárin gbogbo àwọn èyàn nílẹ̀yí lái fi èdè tàbí ẹ̀yà oníkùlùkù se.

idogbe 

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *