Giwa Fasiti Oye Ekiti, Ojogbon Kayode Soremekun, tise agbekale iko eleni mejila kan latise iwadi lesekese lori on to sokunfa ifehonuhan ojo isegun tokoja ati ikolu aya Gomina Ipinle Ekiti, Erelu Fayemi, ati bi awon meji se padanu emi won ninu ikolu naa.

Ninu atejade eyi ti Ojogbon Soremekun fowosi nilu Oye Ekiti ni oro naa ti jade, pelu alaye pe igbese  naa yoo dena irufe rogbodiyan naa lojowaju.

Bakanna lotun benu ate lu isele naa, to si seleri lati mu atunto ba ilana ile eko giga Fasiti naa. Igbimo eleni mejila naa ti yoo se iwadi naa ni Igbakeji alase ile eko naa, Ojogbon AbayomiFashina je alaga fun, ti Arabinrin Blessing EyiOlorunfe si je Akowe.

Ogunkola/Ogunrinde

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *