Àarẹ orílẹ̀dè yíì Muhammadu Buhari ti ké sáwọn ọmọ ilẹ̀ Nàijírìa láti máà dábòbò kíwọ́ sì máà mú àgbéga bá àsà àti isẹ́ ilẹ̀ yíì, pẹ̀lú àtọ́kasípé, látara àsà àti ìse àwọn èèyàn niwọ́n fi máà ń mọ bí ti irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ tiwà.

Lákokò ayẹyẹ ọlọ́jọ́ fún tọdún 2019 tó wáyé láafin Ọọni tìlú ilé-Ifẹ̀, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, làarẹ Buhari ti fidí èyí múlẹ̀ nílé Ifẹ̀.

Àarẹ ẹnití alákoko fọ́rọ̀ abẹ́lé, ọ̀gbẹ́ni Rauf Arẹgbẹsọla sojú fún, sopé, kò sé mọ́ni ni àsà jẹ́ fáwọn èèyàn tíwọ́n si dìjọ máà ńkọ̀wọ́rìn nítorí náà ló fi yẹ kíwọ́n ma mọrímọ̀ rẹ̀.

Àarẹ Buhari wá fìdùnú rẹ̀ hàn fáwọn èèyàn Ilé-Ifẹ̀ lórí bí wọ́n se máà sàmúlò àsà àti ìse ilẹ̀ yíì.

Kẹmi Ogunkọla/Osamudiamen Idemudia

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *