Ìjọba àpapọ̀ ilẹ̀ yíì àti ẹgbẹ́ àwọn òsìsẹ́ ńfikùnlukùn láti fọ̀rọ̀jomito ọ̀rọ̀, lórí àlékún owó osù òsìsẹ́ tówà lákàsọ̀ tókéréjù ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n náirà.

Ìpàdé yíì ló ń wáyé lẹ́yìn ìpàdé èyí tíwọ́n se lána òdeyi níbi tẹ́gbẹ́ àwọn òsìsẹ́ ti fi ìpinu wọn lórí àlékún náà hàn, tí ìpàdé òní sì níse pẹ̀lú ìpinu ìyansẹ́lódì tẹ́gbẹ́ òsìsẹ́ fẹ́ gùnlé lọ́la òde yíì tíjọba bákọ̀ láti fẹnuọ̀rọ̀ kò lóni yíì.

Ẹgbẹ́ àwọn òsìsẹ́ ni àgbáríjọpọ̀ ìgbìmọ̀ tó ńrísí ìdúnadúrà fáwọn òsìsẹ́ yóò sojúfún nípasẹ̀ adelé alága, Achaver Simon àti akọ̀wé ìgbìmọ̀ náà Alade Lawal.

Alákoso fọ́rọ̀ isẹ́ nílẹ̀ yíì, Chris Ngige ti pe àwọn adarí fẹ́gbẹ́ òsìsẹ́ láti péjú síbi ìpàdé ọ̀hún. Kẹmi Ogunkọla/Ọmọlọla Alamu

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *