Ìpàdé lórí ẹ̀kún owó osù oní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n tí ẹgbẹ́ àwọn òsìsẹ́ àti ìjọba gùùnlé ni ó tún ti forí sọ́pọ́n nígbàtí wọ́n ò lee fẹnu kò síbi kan lẹ́yìn wákàtí mẹ́san tí wọ́n ti ńsèpàdé.

Alákoso fọ́rọ̀ àwọn òsìsẹ́ àti ìgbanisísẹ́, Dókítà Chris Ngige nígbàtí ó n bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ nílu Abuja lẹ́yìn ìpàdé ọ̀hún ni wọ́n ti gbé isẹ́ fún àwọn ìgbìmọ̀ kan àti wípé àbájáde àwọn ìgbìmọ̀ ọ̀hún ni wọn ńdúró dè wọ́n tó léè fẹnukò lórí owó osù tuntun ọ̀hún.

Ó ní wọn yóò tun tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìpàdé náà nígbàtí ó bá di áàgo méje àsálẹ́ òní.

Alága ẹgbẹ́ àwọn òsìsẹ́, Ayuba Waba ni àwọn ọmọ ilẹ̀ yí ní wọn yo fi àbájàde ìpàdé ọ̀hún tó létí kété tí wọ́n parí ìpàdé tuntun tí wọ́n fẹ́ se yi.

Kẹmi Ogunkọla/Dada Oluwayẹmisi

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *