Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ, onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde sọpé ètò ìsèjọba tóun ńléwájú rẹ̀ kóní tẹ̀tì láti gùnlé àwọn ìpinnu èyí tí yóò fẹsẹ̀ ìdàgbàsókè tóò lórin múlẹ̀ nípinlẹ̀ Ọyọ.

Ó sọ èyí nígbà tó ńgba àbọ̀ ìwádi ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni méje, èyítí ìsèjọba rẹ̀ gbé kalẹ̀ láti wòye sí oníruru ìpèníjà tó ńkojú ìpínlẹ̀ yíì, lọ́fìsì rẹ̀ nílu ìbàdàn.

Gómìnà Makinde wá bèrè fún àbá látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn àwùjọ láti mú ìpínlẹ̀ Ọyọ gòkè àgbà pẹ̀lú àlàyé pé irúfẹ́ àbá bẹ yóò sisẹ́ lọ́pọ̀ fágbege ìpínlẹ̀ Ọyọ.

Bákanà ni Gómìnà fidá àwọn èèyàn lójú pé, àbọ̀ àwọn ìgbìmọ̀ náà yóò jẹ́ sísàmúlò lárin ọ̀sẹ̀ mẹ́rin.

Gómìnà tọ́kasi pé àbọ̀ ìwádi ìgbìmọ̀ náà tọ́kasi dídá àwọn òsìsẹ́ kan dúró lọ́nà àitọ́, tó sì sàlàyé pé ìjọba yóò ságbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ náà tí yóò sì dá àwọn tóbáyẹ padà sísẹ́ lẹ́yẹ òsokà.

Kẹmi Ogunkọla/Dada Oluwayẹmisi

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *