Yoruba

Egbe Osise Laago Ikilo fun ‘Joba Ipinle Ogun

Are egbe osise orile ede yii, Ogbeni Ayuba Wabba, ti sope oun yio ko awon osise Ipinle Ogun sodi lojo Jimoh lati fehonu han lori liana owo lile to Gomina Ibikunle Amosun na sawon osise ipinle naa.

Ogbeni Wabba woye pe igbese naa yio waye lati jeki Gomina Amosun yanju gbogbo awon gbungbun oro to wa larin egbe osise ati Ijoba Ipinle Ogun.

Asaaju egbe osise ti kowe si Gomina Amosun lati fi to leti nipa ifehonu han naa siwa to lodi ti Ijoba nhu sawon osise.

Gegebi asaaju egbe osise se wi, lara awon ibeere awon osise ni lati da alaga egbe osise ipinle naa Ogbeni Akeem Ambali pada sip o atawon olori egbe osise yoku tijoba re le kuro lenuse.

Awon nkan yoku ni sisan obitibiti owo tiwon yo lona aito , ajesile bi osu merinlelogorun fawon osise pelu sisan owo egbe ati owo ifeyinti tiwon je awon osise feyinti ati owo osu tiwon je awon osise Ilewe Olukoni Tai Solarin, Omu-Ijebu

Ogunkola/Oluokun

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *