Yoruba

Àarẹ Buhari késí ọmọ ilẹ̀yí láti díbò lái fa wàhálà

Àarẹ Muhammadu Buhari ti késí àwọn èèyàn ilẹ̀ Nàijírìa láti tú yáyá jade láti kópa nínú ètò ìdìbò Gómìnà àti ti-ilé ìgbímọ̀ asòfin Ìpínlẹ̀ tí yóò wáyé lọ́jọ́ àbámẹ̀ta yi.

Àarẹ rọ tikere tikere ọmọ ilẹ̀ yi láti jẹ́kí ètò ìdìbò náà lọ nírọwọ́-rọọsẹ̀ gẹ́gẹ́ bí tétò ìdìbò sípò àarẹ se lọ láisi jàgídí-jàgan.

Àarẹ Buhari sàlàyé pé, ètò ìdìbò Gómìnà àti ilé asòfin se pàtàkì gẹ́gẹ́ bí ètò ìdìbò sí ipò àarẹ èyí tó ńpèfún ìtúyáyá jáde àwọn èèyàn àwùjọ.

Àarẹ wá gba àwọn olùdìbò níyànjú láti yàgò fún màgà-mágó lákokò ètò ìdìbò àti jàgídíjàgan tó lè pagidínà ètò náà lọ́jọ́ Àbámẹ̀ta.

Kemi Ogunkọla/Sheriffdeen Nasirudeen

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *