Ilé ẹjọ́ tó ńgbọ́ awuyewuye tó súyọ lásìkò ìdìbò sípò Gómìnà nípinlẹ̀ Ọsun èyí tó jóko nílu Abuja, ni yo gbe ìdájọ́ kalẹ̀ lọ́jọ́ ẹtì tónbọ̀ yi, lórí ẹ̀sùn èyí tí ẹni tó díje lábẹ́ àsía ẹgbẹ́ òsèlú Peoples Democratic Party, PDP, Sẹ́nátọ̀ Ademọla Adeleke, lórí àbájède ìbò tó wáyé nínú osù kẹsan, ọdún tó kọjá.

Àwọn ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́ta, ni wọ́n ti gbọ́ àlàyé lẹ́nu àwọn agbẹjọ́rò lọ́jọ́ keje osù kẹta tawàyí.

Ikọ́ agbẹjọ́rò èyí tí Ibrahim Sirajo léwájú rẹ̀, sọ pé wọ́n yo fún àwọn ẹgbẹ́ méjèjì ní ókérétán wákàtí méjìdínládọta kó tó dipé wọ́n gbé ìdájọ́ kalẹ̀.

Ẹgbẹ́ òsèlú PDP, àti Sẹnátọ̀ Adeleke ló fi ẹ̀sùn kan àjọ INEC, pé àwọn kò faramọ́ ìkéde Àlhájì Adegboyega Oyetọla tẹgbẹ́ òsèlú APC, pe òun ló jáwé olúborí nínú ìbò sípò Gómìnà nípinlẹ̀ Ọsun.

Kemi Ogunkọla/Funmi Adekọya

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *