Yoruba

Àarẹ Buhari yan Adájọ́ tuntun márun

Àarẹ Muhamadu Buhari ti kọ̀wé sí adelé adájọ́ àgbà lórílẹ̀èdè yi, adájọ́ Tanko Muhammad, pé ó fẹ́ yan adájọ́ márun míì síì sí iléẹjọ́ tó gaajù lórílẹ̀èdè yi.

Bákana ni àarẹ Buhari ti tẹ́wọ́ gbáà ìwé ìfẹ́yìntì adájọ́Walter Onnaghen, gẹ́gẹ́bí adájọ́ àgbà orílẹ̀èdè yi.

Àarẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ adájọ́ Onnoghen fún isẹ́ tó se fún orílẹ̀èdè yi, ó sì gbàdúrà pe, kí Ọlọ́run se ọ̀nà rẹ̀ ní rere.

Olùránlọ́wọ́ pàtàkì fún àarẹ lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, Mallam Garba Shehu, sàlàyé pé, àarẹ Bbuhari ní òun fẹ́ kí adájọ́ márun míì kún-ún àwọn adájọ́ tó wà níléẹjọ́ tó gajù lọ lórílẹ̀èdè yi kí wọ́n ba lè pe mọ́kànlélógún gẹ́gẹ́bí ìwé òfin orílẹ̀èdè yi se sọ.

Ó sàlàyé síwájú pé, ìyànsípò àwọn adájọ́ tuntun na yó jé kí ètò ìdájọ́ túbọ̀ ya kánkán, paapa àwọn ẹjọ́ kòtẹ́milórùn.

Ogunkọla/Alamu

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *