Wọ́n ti rọ àwọn olùkópa níbi ètò ìdánilẹ́kọ ọlọ́jọ́ mejì tó níse pẹ̀lú ọ̀nà láti dọlọ́rọ̀ látara èso Jathropha pé kíwọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbin ọ̀gbìn náà láì fàkókò sòfò.

Ètò ìdánilẹ́kọ náà ní ilésẹ́ Radio Nigeria ẹkùn Ìbàdàn sàgbékalẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àjọseps ẹgbẹ́ àwọn àgbẹ̀ Jathropha nílẹ̀ Nàijíríà àti ilésẹ́ Transparent Bio-oil àti gásíì.

Olùdánilẹ́kọ níbi ètò náà onìmọ̀ nípa ọ̀gbìn, ọ̀gbẹ́ni Julius Ogunyẹmi sọpé ọ̀gbìn Jathropha rọrùn púpọ̀ tí ilé kékeré si se lo láti bẹ̀rẹ̀ ọ̀gbìn náà.

Olùdarí àgbà fún ilésẹ́ Premier F.M Ìbàdàn,Ẹniọ̀wọ̀ Niyi Dahunsi gba àwọn olùkópa níyànjú láti má gbàgbé ohun gbogbo tíwọ́n ti kọ́ kíwọ́n sì sàmúlò rẹ̀.

Kẹmi Ogunkọla/Ogunyẹmi

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *