Ìdánileko olọ́jọ́ méjì kan wáyé nílese, Radio Nàìjíríà Ìbàdàn lopopona Ọba Adebimpe Dùgbe Ìbàdàn, lórí ọ̀nà bá ṣe lè sọ èso Jatropha tamosi èso làpá làpá di ọrọ.

Ètò ìdánileko náà èyí tí ilé-isé Radio Nàìjíríà Ìbàdàn pẹ̀lú àjọṣepò ẹgbẹ́ àwọn àgbè ọlọgbin Jatropha tilè Nàìjíríà ló ṣàgbékale rẹ.

Nínú ọ̀rọ̀ ìkíni káàbọ̀ tiẹ̀, olùdarí àgbà ilé-isé Radio Nàìjíríà Ìbàdàn, Alhaji Mohammed Bello ẹnití olùdarí ẹ̀ka tó ń powo wọlé nílese náà arábìnrin Bolanle Owoyemi ṣojú fún, sọ pé, ìdánileko òhún ló jé ọ̀nà láti fowósowopo pẹ̀lú ìlànà tí jọba Àpapọ̀ gbékalè láti máà pawo wọlé lèka ètò ọ̀gbìn dípò epo ròbi.

Alága ẹgbẹ́ àwọn àgbè ọlọgbin Jatropha nílè Nàìjíríà Agba Akin Adeogun Aderemi tókasi pé, èso Jatropha tí wọ́n ń yọ epo jáde látara rẹ tí ń fegbekegbe pé làwọn ọjà tiwọn ń tà sókè òkun, bíi cocoa, Coffee ateso Cashew.

Kemi Ogunkola/Sunday Ogunyemi

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *