September 20, 2020
Yoruba

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọyọ sọ àsọyán lórí àkànse ise ojú ọ̀nà

Kò ní pẹ́ mọ́ọ̀, tí ibùdó alákúta- fakuta àti ìpèsè ọ̀dà kóntà fún isẹ́ ojú ọ̀nà, tí ìpínlẹ̀ Ọyọ, tí wọ́n pè ní “Pacesetters” tó wà lójú ọ́nà Maníyà sí Ìsẹ́yìn, tó ti dakúrẹtẹ̀ lọ́wọ́-lọ́wọ́ báyi, yóò bẹ̀rẹ̀ isẹ́ padà.

Gómìnà Seyi Makinde, tó eléyi di mímọ̀ lákokò àbẹ̀wò níbo ni ǹkan dé dúró níbòdó náà, sọ pé ìjọba fẹ́ ta ibùdá náà ji padà, láti mú àgbéga bá isẹ́ ojú lílà àti síse wọn nípinlẹ̀ Ọyọ.

Gómìnà Makinde, tó bẹnu àtẹ́ lu ipò ìpolúkúrúmusu tí ibùdó náà wà báyi sọpé, òhun tó yẹ kó jẹ́ ǹkan àmúyangàn fún ìpínlẹ̀ Ọyọ, láwọn kan ti fọ̀rọ̀ òsèlú àti àilákàkún so olójòjò, èyí tó wà jẹ́ kí ìjọba ló ma na owóole da sóde láti ra ọ̀dà konta wà fún àwọn àkanse isẹ́ ojú ọ́nà nípinlẹ̀ yíì.

Nígbà tó ńmú Gómìnà Makinde yípo ọgbà ibùdó àlàkúta po ọda náà, olùdarí àjọ tó ńrísí ìgbélárugẹ okòòwò nípinlẹ̀ Ọyọ, arábìnrin Nikẹ Omopemi, sọ pé ńse láwọn olùkókòòwò nkoyin si iléésẹ́ náà nítorí bí ńse rí bó seyẹ kórí nbẹ.

Sáájú ní Gómìnà Makinde ti kọ́kọ́ sàbẹ̀wò àisọtẹ́lẹ̀ sí iléésẹ́ tó ńrísí ẹ̀ka ètò ọ̀gbìn nípinlẹ̀ Òyọ, níbi tó ti pa lásẹ fún akọ̀wé àgbà níbẹ̀ ọ̀gbẹ́ni Victor Atilọla, láti taari àwọn katakata tó kàn wà nílẹ̀ lásán sáwọn ibùdó ọkọ ẹgbẹ́jọdá, lárin ọ̀sẹ̀ mẹ́rin péré.

Gómìnà wá fọwọ́ ìdánilójú sọ̀yà wípé, àkóso tó wà lóde báyi ní ìpínlẹ̀ Ọyọ, yo sa gbogbo ipá rl láti mú àgbéga bá ẹ̀ka ètò ọ̀gbìn nípinlẹ̀ Ọyọ.

Ogunkọla/Adebisi

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *