News

Ọba alayé pè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láti mú Nàìjríríà gòkè àgbà

Ọọni ilé ifẹ̀, Ọba Adeyẹye Ogunwusi ti sọ pé, ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba yóò mú kí orílẹ̀èdè Nàijíríà gòkè àgbà.

Ọba Ogunwusi sọ̀rọ̀ yi nílu Abẹ́okuta nígbá tó sàbẹ̀wò sí Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ògùn, ọmọọba Dapọ Abiọdun.

Ọba alayé náà késí tíkere tikere ọmọ ilẹ̀ yi láti se àtìlẹ́yìn fáwọn tó dipò ìjọba mú kí ìdàgbàsókè tó gbọngbọ́n lè bá ilẹ̀ Nàìjíríà.

Nígbà tó ńsọ̀rọ̀, Gómìnà Dapọ Abiọdun sọ pé ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn yóò se ìdásílẹ̀ ibùdó àsà àti ìse gẹ́gẹ́bí ọ̀nà láti mú àgbéga bá àsà ilẹ̀ wa.

Kẹmi Ogunkọla/Bolanle Adesida

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *