Yoruba

Ìjóba àpapọ̀ ńpiyamọ ètò ìdásílẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ nípa ìmò ẹ̀rọ

Gẹ́gẹ́bí ara ìgbékalẹ̀ láti ró àwọn ọ̀dọ́ lágbára nípasẹ̀ ìmọ̀ ẹ̀rọ òde òní, ìjọba àpapọ̀ ti ńpiyamọ ètò láti se ìdásílẹ̀ àwọn ilé ẹ̀kọ́ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ mẹ́fà ọ̀tọ̀tọ̀ láwọn ibìkan nílé kọ́dún yíì tó wá sópin.

Mẹ́wa irúfẹ́ àwọn ilé ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀, yóò tun jẹ́ dídá sílẹ̀ si láarin ọdún mẹ́ta sí àsìkò táà wà yíì, láti fi àwọn ọ̀dọ́ mọ ọ̀nà tí wọn yóò filè dá dúró fúnrawọn di agbanisísẹ́.

Èyí lohun tó jẹyọ látọ̀dọ̀ akọ̀wé àgbà iléesẹ́ ètò ẹ̀kọ́ ìjọba àpapọ̀, ọ̀gbẹ́ni Sonny Echono nílu Abuja lákoko tó ńtẹ́wọ́ gba àbọ̀ méjì ọ̀tọ̀tọ̀, tíjọba gbé kalẹ̀ lórí àmúgbòòrò ètò ìkọ́ni nípa ìmọ̀ èrọ àti ìkọ́ni nísẹ́ ọwọ́.

Ọjọ́ kẹrin osù kẹrin ọdún yíì nìjọba se ìfilọ́lẹ̀ ìgbìmọ̀ kan tó sisk lórí ìlànà ìkọ́ni nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ, tó sì gbe èyí tó sisẹ́ nípa ìlànà ìkọ́ni lẹ́kọ isẹ́ ọwọ́ kalẹ̀ lagbọnjọ́, osù kẹrin ọdún yíì kan náà.

Ojúse ìgbìmọ̀ méjèèjì sì ni láti gba ìjọba nímọ̀ràn nípa àgbékalẹ̀ ọ́nà ọ̀tun láti ró àwọn ọ̀dọ́ lágbára fún àmúgbòòrò ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀èdè yíì.

Babatunde Tiamiyu    

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *