Awọn Gómìnà káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà lẹ́kùn ìwọ̀orùn orílẹ̀èdè yíì ti fẹ́ parí ìlànà ètò ààbò alájùmọ̀se

Bí ọ̀rọ̀ ìpèníjà ètò àbò se ńdi ìràwọ̀ ọ̀sán lórílẹ́èdè yíì, bẹ́ẹ̀ náà làwọn Gómìnà káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tó wà lẹ́kùn ìwọ̀orùn orílẹ̀èdè yíì ti fẹ́ parí ìlànà gbogbo láti se ìfilọ́lẹ̀ ètò ààbò alájùmọ̀se fún àabò ẹ̀mí àti dúkia lẹ́kùn náà.

Ìgbésẹ̀ èyí ló tẹ̀lé bí iléésẹ́ olùdámọran lórí ọ̀rọ̀ àabò fún àpapọ̀ orílẹ̀èdè se ti buwọ́lù pé kí ẹkùn náà se ìdásílẹ̀ ikọ̀ láabo amúsẹ́yá alájùmọ̀se láti gbógun ti àwọn ìsẹ̀lẹ̀ ìpèníjà bíì, ìpànìyàn, ìdigunjalè àti ìjínigbé tó ńdi gbọnmọ-gbọnmọ lẹ́kùn ìwọ̀orùn gúúsù ilẹ̀yí.

A ó ranti pé lósù keje ọdún yíì làwọn Gómìnà lẹ́kùn ìwọ̀orùn gúusù orílẹ̀èdè yíì se ìpàdé kan nílu ìbàdàn, níbi tí gbé fẹnukò láti jùmọ̀ gbe ìlànà ètò a ó àjọse lẹ́kùn náà.

Ìròyìn tí ẹ sọ di mímọ̀ wípé, àwọn Gómìnà náà ti ra àwọn ọkọ̀ àgùnbẹ́ fún ìparaarọ ààbò lọ́pọ̀ jaburata sílẹ̀ sáájú ìfilọ́lẹ̀ ikọ̀ elétò àabò alájùmọ̀se náà, kó tó osù kẹwa ọdún yíì tí wọ́n se ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀.

Babatunde Tiamiyu    

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *