Adarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ Ọyọ, ọ̀gbẹ́ni Debọ Ogundoyin ti gba alága àtàwọn ìgbìmọ̀ tẹkótó ilé ẹlẹ́ni márùndínlọ́gbọ̀n níyànjú láti sisẹ́ wọn bí isẹ́.

Adarí ilé gbé àmọ̀ràn yíì kall lákokò tó ńbura fún ìgbìmọ̀ náà níbi ètò kan èyí tí pínpín ìwé òfin àtẹ̀lée fáwọn ìgbìmọ̀ ọ̀hún tí wáyé níbẹ̀ pẹ̀lú.

Ó sàlàyé pé ojúse àti ìgbésẹ̀ ìgbìmọ̀ yíì sepàtàkì fún ìfẹsẹ̀múlẹ̀ asori ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ Ọyọ.

Nínú ọ̀rọ rẹ̀, asojú tẹ́lẹ̀ nílé-ìgbìmọ̀ asojú sòfin, ọ̀mọ̀wé Wale Okediran sọpé ìgbìmọ̀ ilé ma ńsisẹ́ tó sísegbẹ́kẹ̀lé àwọn ohun tó se pàtàkì jùlọ fún ilé bí síse àgbéyẹ̀wò, ìdúró-réè, àti sósọ àbá dòfin láti sètò ìjọba nípinlẹ̀.

Kemi Ogunkọla/Mosope Kẹhinde

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *