Àwọn asòfin ní ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ Ọyọ ńsètò ìpàdé ọlọ́jọ́ mẹ́rin lọ́wọ́ báyi lórí àbá òfin mẹ́ta kan tó sepàtàkì.

Àwọn àbá òfin ọ̀hún ni, àbà tóníse pẹ̀lú àgbéga àjọ tó ń dá isẹ́ ajé sílẹ̀ ọdún 2019, àbá tí níse pẹ̀lú àjọ tó ńgbóguntí ìwà àbàjẹ́ tófimọ́ àbá tóníse pẹ̀lú àtúntò àti ìdúró réè ìgbésẹ̀ ohun ọ̀gbìn kíkó ẹranjẹ̀ ni yóò jẹ sísọ̀rọ̀ lélórí níbi ìpàdé ọlọ́jọ́ mẹ́rin náà èyí tó ńlọ lọ́wọ́ ní Resort Centre nílu ìbàdàn.

Nígbà tó ńsí ìpàdé náà, adarí ilé ọ̀gbẹ́ni Adebọ Ogundoyin ẹnitósọpé àbá àtúntò àti ìdúró re isẹ́ ọ̀gbìn àti ìkó ẹranjẹ̀ fáwọn àgbẹ̀ àti darandaran wáyé nípinlẹ̀ Ọyọ láti dẹ́kun rògbòdìyàn, sọpé ilé yóò gbe ìgbésẹ̀ tóyẹ lórí ọ̀nà àbáyọ.

Bákanna, alága ìgbìmọ̀ tẹkòtò ilé fọ́rọ̀ isẹ́ àti ètò ìrìnà, asojú ẹkùn ìdìbò ìbàdàn North east 1, ọ̀gbẹ́ni Ọlmide Akinajọ sọpé ètò ìsèjọbatówà lóde báyíì nípinlẹ̀ Ọyọ ńléwájú lórí àbá òfin gbígbógunti ìwà àjẹbánu léyi tó fọwọ́sọ̀yà pe tóbá dòfin tán yóò tọwọ́ ọmọ ìwà ìbàjẹ́ bọ́sọ nípinlẹ̀ Ọyọ.

Kẹmi Ogunkọla/Adebisi    

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *