Yoruba

Iléésẹ́ ológun júwe ilé fáwọn òsìsẹ́ taje ìwà ìbàjẹ́ si mọ́ lórí

Ilẹ́ẹ́sẹ́ ológun orílẹ̀èdè yi sọ pé, òun ti gbasẹ́ lọ́wọ́ àwọn sọ́jà mẹ́ta kan tí wan wà lára àwọn ọmọ ikọ̀ ajínigbé, tọ́wọ́ báà, lẹ́yìn odi ìlú Maiduguri.

Ọgaologun fún ikọ̀ Lafiya Dole, ọ̀gágun Olusẹgun Adeniyi ló kéde ọ̀rọ̀ yí, nígbàtí ń fáà àwọn ọlọ́pa lọ́wọ́ nílu Maiduguri.

Ọgagun Adeniyi sọ pé, nínu ilé kan tó wà lẹ́yìn odi ìlú Maiduguri ni ọwọ́ ti tẹ̀ẹ̀ àwọn sójà na, pẹ̀lú àwọn méjìlélógún níì tí wọ́n fura sí pé ajínigbé ni wọ́n.

Ó sàlàyé pé, ikọ̀ Lafiya Dole làwọn sọ́jà mẹ́tààta na ń bá sisẹ́ kó tó dipé, wọ́n tún lọ sọ pànpá pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀daràn tó ń jínigbé tí wọ́n dingunjalè àtàwọn ìwàburúkú mi.

Níbàyíná alákoso fún iléésẹ́ ọlọ́pa nípinlẹ̀ Borno, ọ̀gbẹ́ni Mohamed Aliyu sọ pé, èèyàn mẹ́ẹ́dọgbọ̀n tó ‘’n dúnkokò wọ́ àwọn èèyàn ìlú Maiduguri àti agbègbè rẹ̀, láwọn ọlọ́pa ti mú.

Kẹmi Ogunkọla/Tọba

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *