Yoruba

Àjọ JAMB gbé ìgbésẹ̀ láti dénà màgòmágó ìdánwò

Àjó tó ń rí sétò ìdánwò ìgbaniwọ́ló sáwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga Jamb ti ké sáwọn akẹ́kọ tí yóò jóko se ìdánwò UTME, tọdún 2020, láti lọ gba núnber ìdámọ̀ ọmọ ilẹ̀ yíì.

Agbẹnusọ fájọ ọ̀hún, ọ̀mọ̀wé Fabian Benjamin sọ pé, èròngbà ìgbésẹ̀ náà ni latirí dájú pé, gbogbo àwọn àkọsílẹ̀ tóyẹ nípa àwọn akẹ́kọ náà ló pé sórí ẹ̀rọ ayélujára, láti dènà ìgbésẹ̀ màgòmógó síse nínú ìdánwò.

Àtẹ̀jáde kan tíwọ́n fisita nílu Èkó pé, ló ti sàlàyé pé ìgbésẹ̀ náà se pàtàkì gẹ́gẹ́ bó se jẹ́pé ètò ìforúkọsílẹ̀ fún ìdánwò UTME ọdún 2020 ti bẹ̀rẹ̀ báyíì.

Ọmọwe Benjamin kò sài tún sọ́ọ́di mímọ̀ pé, àjọ Jamb ti gùnlé àwọn ètò tó yẹ pedajọ NIMC fáwọn akẹ́kọ tó fẹ́ sàdánwò náà láti sètò ìforukọsílẹ̀ wọn láwọn ibùdó ìdánwò.

Kẹmi Ogunkọla/Dada Yẹmisi

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *