Yoruba

Gomina Makinde yan Ọ̀mọ̀wé Babatunde ni Olùbádámọ̀ràn Fétò Ọrọ́ Ajé

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ, onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde ti fọwọ́sí ìyànsípò onímọ̀ nípa ètò ọ̀rọ̀ kan látẹ̀ka tíwọ́n ti ńkọ́ nípa ìmọ̀ nípa ọrọ̀ ajé nílé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ìbàdàn, ọ̀mọ̀wé Musibau Babatunde gẹ́gẹ́bí olùbádámọ̀ràn pàtàkì rẹ̀ fétò ọrọ́ ajé.

Àtẹ̀jáde kan tákọ̀wé àgbà sígómìnà fétò ìròyìn, ọ̀gbẹ́ni Adisa fisita só pé, ìyannisípò ọ̀mọ̀wé Babatunde náà lóníse pẹ̀lú bí bẹ̀rẹ̀ isẹ́ lẹ́yẹ òsọkà.

Gómìnà Makinde tó ti kéde èròngbà ìdàgbàsókè mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó ní fún ìpínlẹ̀ Ọyọ ló ti darikọ ẹ̀ka ètò ọ̀rọ̀ ajé gẹ́gẹ́bí ọ̀kan gbogì nínú àwọn òpó tó gbé ìpínlẹ̀ yíì ró.

Kò sài tún kí olùbádámọ̀ràn tuntun náà kú oríire ìyànsípò rẹ̀, tó sì gbàdúrà àseyọ́rí tó lóórin fún láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ lórí ọ̀nà táyipadà rere yóò fi débá ìpínlẹ̀ Ọyọ.

Ọmọwe Babatunde ẹni tó gba ìrànlọ́wọ́ ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́, láti gba oyè ọ̀mọ̀wé, lọ́dọ̀ àgbáríjọpọ̀ àjọ olókoowò àgbáyé, nílu Geneva, lórílẹ̀èdè Swizerland, lósù kẹsan ọdún 2005, kàwé nílé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ìbàdàn níbi tó ti gba oyè àkọ́kọ́ nínú ẹ̀kọ́ nípa, ètò ọrọ̀ ajé.

Kẹmi Ogunkọla/Yẹmisi Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *