Yoruba

Ilé Asòfin Sèlérí Ibuwọ́lù Ofin ẹ̀ka Epo Rọ̀bìi.

Àarẹ ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà, Ahmed Lawan, sọ pé, ilé asòfin náà yóò buwọ́lu àbá òfin tóníse pẹ̀lú ilé-isẹ́ epo bẹntiro, PIB, kó tó dìparí ọdún 2020.

Nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọrẹ̀ lákokò tó ń sèfilọ́lẹ̀ àadọ́rin ìgbìmọ̀ tẹ̀kótó ilé asòfin àgbà níbi ìjóko ilé tó wáyé nílu Abuja ni asòfin Lawan ti fìdí èyí múlẹ̀.

Ó wá ké sáwọn aláábo tóníse pẹ̀lú àwọn ìgbìmọ̀ náà láti sisẹ́ papọ̀ pẹ̀láwọn àjọ aláábo tókù, lórí ọ̀nà tíwọ́n yóò fi kápá àwọn ìpèníjà tón kojú ètò àabò orílẹ̀èdè yíì.

Dada Yẹmisi/Akintunde     

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *