Yoruba

Sanwoolu sàbẹ̀wò àìròtì sílé ẹ̀kọ́ girama kékeré nílu èkó

Gómìnà Babajide Sanwoolu ti ìpínlẹ̀ Èkó ti tẹnumọ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú isẹ́ àgbẹ̀ ìgbàlódé.

Gómìnà Sanwoolu sọ èyí di mímọ̀ nígbàtí ó ńkọ́ àwọn akẹ́kọ nípele ẹ̀kọ́ girama kékeré kejì àti ìkẹ́ta nílé ẹ̀kọ́ girama Oregun lágbègbè Ìkẹjà nílu Èkó.

Ọgbẹni Sanwoolu ló sàbẹ̀wò àiròtẹ́lẹ̀ sílé ẹ̀kọ́ náà láti mọ̀ bí ǹkan séè ńlọ si láwọn ilé ẹ̀kọ́ ìjọba nípinlẹ̀ náà tó wá lo ànfàní náà láti kọ́ àwọn akẹ́kọ lórí ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ọ̀gbìn àti ìbágbépọ̀ ẹ̀dá.

A ó rántí pé, irúfẹ́ ìsẹ̀lẹ̀ yi sẹlẹ̀ nípinlẹ̀ Ọsun níbi tí akójanu ilé ìgbìmọ̀ asòfin nípinlẹ̀ náà, ọ̀gbẹ́ni Tunde Ọlatunji náà ti yọ̀nda ara rẹ̀ láti máà kọ́ àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ lẹ́kùn ìdìbò rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ ìsirò àti ìbágbépọ̀ ẹ̀dá, ojúse àti ẹ̀tọ́ ìlú ti a man si Civic Ẹducation.

Kẹmi Ogunkọla/Dada Yẹmisi

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *