Yoruba

Àarẹ Buhari bèèrè fún ìdápadà àwọn dúkia tí àwọn kan kósálọ

Àarẹ Muhammadu Buhari ti bèrè fún ìsọ̀kan lárin àwọn orílẹ̀dè ilẹ̀ adúláwọ̀, lọ́nà àti lè lánfàní àtigba àwọn dúkia wọn tí ótijẹ́ jíjíkólọ sórílẹ̀ẹ̀dè ibòmíràn padà.

Àrẹ sọ yíì níbi ètò kan tójẹ́ gbígbékalẹ̀ lórí síse ètò ìsúná lọ́nà àitọ́, níbi IFFS, ìpàdé ilé ìgbìmọ̀ asòfin àjọ ìsọ̀kan àgbáyé tó ńlọ lọ́wọ́ ní New York ẹlẹ́kẹrìnléládọrin irú rẹ̀.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, àarẹ Buhari sọpé, ilẹ̀ Nàijírìa pàdánù owó tóléní àdọ́jọ biliọnu dọllar sí IFFS lárin ọdún 2003 sọ́dún 2012.

Ó wá sàlàyé pé, lóótọ ètò ìsèjọba tóun ńléwájú ti gba òbítíbitì owó ilẹ̀ yíì tíwọ́n tijíkó padà àmọ́ ọ̀pọ̀ owó tójẹ́ torílẹ̀dè Nàijírìa sìwà láwọn ilé ìfowópamọ́ ilẹ̀ òkèrè.

Kẹmi Ogunkọla/Tọba Dupẹ

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *