Yoruba

Ilẹ̀ South Africa tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ ilẹ̀ Nàijírìa

Àarẹ ilẹ̀ South Africa, Cyril Ramaphosa ti tọrọ àforíjìn lórí ìkọlù àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàijírìa tó ńgbé ní South Africa.

Eléyi wáyé níbi ìjókosọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú àarẹ ilẹ̀ Nàijírìa Mohammadu Buhari nílu Pretoria.

Àarẹ Buhari wá rọ ilẹ̀ South Africa láti sètò àabò tó nípọn yíká àwọn iléésẹ́ ńlá ńlá tó jẹ́ tọmọ ilẹ̀ òkèèrè paapa jùlọ ní Johanesburg.

Bákannà àarẹ Buhari tún kìlẹ̀ lórí gbígbẹ̀san lára iléésẹ́ tó jẹ́ ti South Africa, torípé aforó ya oró kíì jẹ́ kí ọ̀rọ̀tan.

Kẹmi Ogunkọla/Akintunde

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *