Yoruba

Àjọ EFCC, kọ̀wé sílé ẹjọ́ láti gbẹ́sẹ̀ le dúkia Maina

Àjọ tó ń rísíẹ̀ sùn sísowóìlú kúmọkùmọ EFCC, ti kọ̀wé sí iléẹjọ́ láti gbẹ́sẹ̀ le àwọn dúkia tí wan ní wọ́n tọpinpin dé ọ̀dọ ẹni tó ti fìgbà kan ríì jẹ́ alága àjọ tó fẹ́ sàtúntò si ọ̀rs owó àwọn òsìsẹ́ fẹ̀yìntì, ọ̀gbẹ́ni Abdurasheed Maina.

Bákannà ni àjọ EFCC, tún ti gba àsẹ láti fíì ẹni tó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ igbákejì olùdarí àjọ tó ń bójútó ọ̀rs owó ìfẹ̀yìntì àwọn òsìsẹ́ asóbọdè àti òsìsẹ́ tó ń bójútó ọgbà ẹ̀wọ̀n sí ìhámọ́ wọ́n, lẹ́yìn tí wọ́n lọ mu ní ilé ìtura kan nílu Abuja.

Ẹni kan tó ń sisẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àjọ EFCC, sọ pé, àjọ na ti ríì àwọn ilé lórísirísi tó wọ́n tóò ọ̀pọ̀lọpọ̀ milliónu náirà tí wọ́n ní ó jẹ́ ti ọ̀gbẹ́ni Maina.

Kẹmi Ogunkọla/Famakin    

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *