Ìjọba àpapọ̀ fún alákoso fétò ọ̀gbìn tẹ́lẹ̀rí lásẹ láti díje fún pò Bánki adúláwọ̀

Àarẹ Muhammadu Buhari tiya ọ̀mọ̀wé Akinwumi Adesina pé kó tún díje fún ipò alákoso àjọ bánki ill Africa tó ń bójútó ọ̀rọ̀ ìdàgbàsókè Africa.

Ọmọwe Akinwumi fún ráà rẹ̀ ló kéde ọ̀rs yi níbi àpéjọpọ̀ kan nílu Èkó.

Ọmọwe Akinwumi tó ti fìgbà kan rí jẹ́ alákoso fọ́rọ̀ isẹ́ àgbẹ̀ àti ìdàgbàsókè ìgbèríko lórólẹ̀èdè yí, wá dúpẹ́ lọ́wọ́ àarẹ Buhari fún ànfàní tó fún ná.

Ọdún 2015 ni wọ́n kọ́kọ́ dìbò yan ọ̀mọ̀wé Akinwumi gẹ́gẹ́bí ọmọ orílẹ̀èdè Nàijírìa àkókò tí yo jẹ́ alákoso bánki ilẹ̀ adúláwọ̀ ọ̀ún èyí tí wọ́n ti dá sílẹ̀ latọdún 1964.

Kẹmi Ogunkọla/Olarinde

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *