Adarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ Ọyọ, ọ̀gbẹ́ni Adebọ Ogundoyin ti ké sí ilé asòfin àgbà àtilé asòfin kejì ilẹ̀ yíì, láti sa ipa wọn lórí ètò ìrólágbára fáwọn ọ̀dọ́ àtàwọn obínrin ilẹ̀ Nàijírìa.

Níbi àpérò kan tó wáyé nílu Abuja lórí ètò ọrọ̀ ajé ilẹ̀ yíì, ẹlẹ́kẹẹdọ́gbọ̀n iruẹ, lọ̀gbẹ́ni Ogundoyin ti bèèrè féyi, pẹ̀lú àtọ́kasipé, ìjọba orílẹ̀èdè yíì nílò láti pèsè isẹ́ lọ́pọ̀ yanturu fáwọn ọ̀dọ́.

Nígbà tó ń báwọn oníròyìn sọ̀rọ̀, ó ní ìgbésẹ̀ ó kéré láti dipò àkóso kan mú se àtẹ́wọ́gbà, àmọ́ ó se se kó máà to fétò ìrónilágbára àwọn ọ̀dọ́ ọ̀hún.

Ọgbẹ́ni Ogundoyin kò sài sọ́ọ̀di mímọ̀ pe, àwọn Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ àti Kwara lágbára tó láti lọ́wọ́ àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn obìnrin sínú ètò ìsèjọba.

Kẹmi Ogunkọla/Adebisi

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *