Yoruba

Àjọ NECO yọ orúkọ ilé ẹ̀kọ́ mẹ́ta kúro lórí ẹ̀sùn màgòmágó

Àjọ tó ń rí sétò ìdánwò oníwe mẹ́wáà, nílẹ̀ yíì, NECO, ti yọ orúkọ àwọn ilé-ìwé mẹ́ta kan látawọn ìpínlẹ̀ bi Kastina, Kebbi, àti Ọyọ kúrò lára àwọn ilé-ìwé tí yóò máà se ìdáwọn  ọ̀hún, fódidi ọdún méjì gbáko lórí ẹ̀sùn bíwọ́n se, ni wọ́n lọ́wọ́ nínú mágòmágó síse nínú ìdánwò.

Adelé akọ̀wé àjọ NECO, ọ̀gbẹ́ni Abubarkar Gana ló fojú ọ̀rọ̀ yíì lánde nílu Abuja, lákokò tó ń jábọ̀ fálakoso fétò ẹ̀kọ́ nílẹ̀ yíì, ọ̀gbẹ́ni Adamu Adamu, lórí àseyọ́rí àjọ ọ̀hún láàrin osù karun ọdún 2018 sí osù tókọjá nínú ọdún yíì.

Ó fi kálàyé rẹ̀ pé, ọ̀kan-ọ̀jọ̀kan àkọsílẹ̀ làjọ náà ti se lórí síse mágòmágó nínú ìdánwò látara lílọ́wọ́ àwọn olùbẹ̀wò olùkọ́ àtàwọn alábojútó irúfẹ́ àwọn ilé-ìwé bẹ́ẹ̀.

Adelé akọ̀wé àjọ NECO, wá késíjọba láti mọ́rọ̀ ètò àbò àwọn ìdánwò lọ́lọ́kan òjọ̀kan tófimọ́wọn alábojútó rẹ̀ lọ́kunkúndùn gẹ́gẹ́ bó se jẹ́ pé, wọ́n ń pèsè ètò àbò tó gúnmọ́ fájọ elétò ìdìbò ilẹ̀ yíì lákokò ìdìbò.

Kẹmi Ogunkọla/Ọlarinde

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *