Yoruba

Ìjọba àpapọ̀ nfẹ́ kájọ ECOWAS gbé ìgbésẹ̀ lórí ìkọlù àwọn arìnrìnàjò

Alákoso fọ́rọ̀ abẹ́lé nílẹ̀ yíì, ọ̀gbẹ́ni Rauf Aregbẹsọla ti ké sájọ tó ń rí sétò ọ̀rọ̀ ajé ilẹ̀ Adúláwọ̀, Ecowas, láti gbé ìgbésẹ̀ kánmọ́ ńkía lórí ọ̀rọ̀ ìwọlé jáde lórílẹ̀dè yíì, láti dènà àwọn ìròyìn tí kò lẹsẹ̀ ń lẹ̀, tàbí èyí tí kíì se òdodo.

Ọgbẹ́ni Arẹgbẹsọla tó sísọ lójú ọ̀rọ̀ yíì lákokò tó ń báwọn olùkópa níbi àpérò ẹlkkùnjẹkùn ọlọ́jọ́ méjì sọ̀rọ̀, lórí ìwọlé-jáde lẹ́kùn ìwọ́ọ̀orùn ilẹ̀ adúláwọ̀, àwọn ìpèníjà tó ń kojú rẹ̀ àtojútu nílu Abuja kọminú lórí éèbu ẹ̀yìn ẹ̀yìn tí ìkọlù àwọn arìnrìnàjò tó wáyé lẹ́nu lọ́ọlọ́ yíì lọ́kan òjọ̀kan àwọn orílẹ̀dè ti fàkalẹ̀.

Ọgbẹ́ni Arẹgbẹsọla, ẹnití olùdarí àgbà pátápátá ilé-isẹ́ tó ń rí sọ̀rọ́ ìwọlé jáde nílẹ̀ yíì, NIS, ọ̀gbẹ́ni Mohammed Babandede sojú fún, sọ pé orílẹ̀dè yíì ti ń gbé ìgbésl láti wójùtú sọ̀rọ̀ àwọn ìpèníjà tó n wáyé lórí ìwọlé jáde lórílẹ̀dè, pẹ̀lú àfikún pé, òun kò fojú kéré ẹ̀tọ́ àwọn arìnrìnàjò ọ̀hún.

Kẹmi Ogunkọla/Olarinde

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *