Yoruba

Ilé asòfin àgbà yóò jíròrò lórí àbá ìsúná ọdún 2020

Ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà ilẹ̀ yíì sọ pé, tó bá di ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n osù kọkọ̀nlá, ọdún yíì làwọn yóò fàbá ètò ìsúná ọdún 2020 sọwọ́.

Alága ìgbìmọ̀ tẹkoto ilé fétò ìròyìn àtọ̀rọ̀ tójẹmọ́ araalu, ọ̀gbẹ́ni Benjamin Kalu, ló fojú ọ̀rọ̀ yíì lánde lákokò tó ń báwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn àgbékalẹ̀ àbá ètò ìsúná látọwọ́ àarẹ Muhammadu Buhari.

Ó sọ́ọ̀di mímọ̀ pe, àwọn asòfin ọ̀hún ti pinnu láti dá àbá ètò ìsúná náà padà sí bó se wà tẹ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti osù kinni ọdún osù kejìlá ọdún.

Ọgbẹ́ni Kalu sọ pé, òun atọla nílé asòfin àgbà náà yóò jíròrò lórí àwọn ìlànà àtòfin tí yóò rọ̀ mọ́ àbá ètò ìsúná ọ̀hún lẹ́yìn èyí ni wọ́n yóò ka fún igbákejì tíwọn yóò sì fi sọwọ́ sígbìmọ̀ tẹkótó ilé tọ́rọ̀ kàn.

Kẹmi Ogunkọla/Olarinde

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *