Ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga, ASUU, ti bẹ̀rẹ̀ ìpàdè àláafìa pẹ̀lú àwọn igun kan nínú ẹgbẹ́ náà tó ti ya tí wọ́n ńpè ni àgbáríjọ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga, Congress of University Academic pẹ̀lú èrò wípé wọ́n yio darí padà sínú ẹgbẹ́.

Àarẹ  àpapọ̀ ẹgbẹ́ ASUU, ọ̀jọ̀gbọ́n Biọdun Ogunyẹmi ẹnití ó sọ èyí di mímọ̀ ni àwọn àgbààgbà inú ẹgbẹ́ ni wọ́n ǹpẹ̀tù sọ̀rọ̀ náà.

Ọjọgbọn Ogunyẹmi ẹnití kò kéde orúkọ àwọn tó gbé ọ̀rọ̀ náà rù ní ọ̀pọ̀ olùkọ́ láwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga ni wọ́n sí wà nínú ẹgbẹ́ ASUU.

Akọ̀ròyìn ilé isẹ́ Radio Nigeria ríì gbọ́ wípé àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga Ọbafẹmi Awolọwọ ilé-Ifẹ̀ àti ti Ambrose Alli nípinlẹ̀ Ẹdo ni wọ́n tin fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó yalọ láti léè wá ojútu sí ọ̀rọ̀ náà.

Oluwayẹmisi Dada/Kẹmi Ogunkọla

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *