Yoruba

Ilé asòfin ìpínlẹ̀ Ọyọ gbé ìgbésẹ̀ lórí ìpèsè iná ọba

Ìlé asòfin ìpínlẹ̀ Ọyọ ti ké sálákoso fọ́rọ̀ ohun àmúsagbára, ọ̀gbẹ́ni  Seun Ashamu, àwọn òsìsẹ́ ilé-isẹ́ tón rí sọ́rọ̀ ohun àmúsagbára àti ìgbìmọ̀ tó ń rí sọ́rọ̀ iná ọba láwọn agbègbè ìgbèríko nípinlẹ̀ Ọyọ láti wá farahàn níwájú ilé, lórí bíwọ́n se páwọn ẹ̀rọ afúnálágbára Transformer kan tì, láiri wọn yíká àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tón bẹ nípinlẹ̀ Ọyọ.

Lákokò ìjọba ilé tó wáyé niwọ́n fìdí èyí múlẹ̀, tí wọ́n sì kọminú lórí báwọn ẹ̀rọ afúninálágbára ọ̀hún se jẹ́ pípatì látọ̀dọ̀ àwọn alásẹ tọ́rọkàn  látọdún 2011.

Nínú àbá alájùmọ̀ gbékalẹ̀ kan, látọ̀dọ̀ ọ̀gbẹ́ni Julius Okeyọyin tó ń sojú ìdìbò ìwọ̀ oorun Sakí, àtsgbẹ́ni Abiọdun Fadeyi tó ń náà ńsojú ẹkùn ìdìbò Ọna àrà tófimọ́ ọ̀gbẹ́ni Kazeem Ọlayanju fẹ́kùn ìdìbò Ìrẹ́pọ̀/Ọlọ́runsògo niwọ́n ti dìjọ sàpèjúwe iná ọba, gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò se máà ni nídi ìdàgbàsókè ètò ọrọ̀ ajé òhun amúludùn léyikéyi ìpínlẹ̀.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ adarí, ilé asòfin náà, ọ̀gbẹ́ni Adebọ Ogundoyin sàlàyé pé, àwọn èèyàn ilé-isẹ́ àtàwọn àjọ tọ́rọ̀ náà kàn gbọdọ̀ farahàn níwájú ilé lọ́jọ́ ìsẹ́gun tí ì se ọjọ́ karun osù kọkànlá láti wá wí tẹnu wọn lórí bí isẹ́ àkànse náà se dàpatì.

Kẹmi Ogunkọla/Adebisi

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *