Yoruba

Aisha Buhari se ìpolongo ìgbógúnti ìkú ìyálọ́mọ

Aya àarẹ ilẹ̀ yíì, Arábìnrin Aisha Buhari ti sèfilọ́lẹ̀ ètò ìpolongo tó dá lórí àti jẹ́kí ìrẹ́pọ̀ wà láarin àwọn abiyamọ àtàwọn ọmọ tuntun, pẹ̀lú ètò ìlara àwọn èwe tófimọ́ dídènà àisàn ibà, àti sisọnọ lórí óunjẹ afáralókun lábẹ́ ètò kan soso.

Arábìnrin Buhari ẹnití aya Gómìnà ìpínlẹ̀ Kẹbbi, ọ̀mọ̀wé Zainab Bagudu, sojú fún sọpé, ètò ìlera àwọn ọmọdé àti tàwọn alábiyamọ tí kojú onírunru àyípadà rere, èyí tó ti pakun ìlọsíwájú àti ìdàgbàsókè orílẹ̀dè lẹ́nu lọ́ọ̀lọ́ yíì.

Aya àarẹ ilẹ̀ yíì sàlàyé pé, àwọn kùdìẹkudiẹ kan máà ń wáyé lẹ́ka ìbímọ àwọn aláboyún bí ọ̀dá owó àisáwọn ohun amáyédẹrùn àtohun àmúsagbára.

Kò sài sọ́ọ̀di mímọ̀ pe, àjọ kan tí Aisha Buhari gbékalẹ̀ ti sàgbékalẹ̀ àwọn ètò kan èyí táfojúsùn rẹ̀ dá lórí àbò ẹ̀mí àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé níbamu pẹ̀lú wíwá ojútu sọ́kan òjọ̀kan àwọn ìpèníjà tó máà ń wáyé lákokò ìbímọ, ìlóyún, tọmọtuntun, ìlera àwọn ọmọdé àtàwọn àgbàlagbà.

Kẹmi Ogunkọla/Famakin

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *