Wọ́n ti rọ àwọn èèyàn ilẹ̀ yíì, láti ma sọ́rase lórí ìgbé-ayé wọn àti irúfẹ́ ónjẹ tí wọ́n yóò ma jẹ, lọ́nà àto dènà bíbọ́ sí pánpẹ́ àisàn ìtọ̀ súgàr.

Àarẹ ẹgbẹ́ àwọn tóní ìtọ̀ sugar, olóyè Emmanuẹl Adeyinka sọ̀rọ̀ àmọ̀ràn yíì níbi ètò àyẹ̀wò ìlera ọ̀fẹ́ ọlọ́jọ́ kan, èyítí ẹgbẹ́ àwọn olùgbé agbègbè Sango nílu ìbàdàn se àgbékalẹ̀.

Olóyè Adeyinka sàlàyé pé, àisàn ìtọ̀ sugar ti ńgbalẹ lórílẹ́èdè yíì, nítorí táwọn èèyàn ńkùnà láti gbé ìgbé-ayé ìlera tópeye, nípasẹ̀ jíjẹ́ àti mímú àwọn ohun tóle fáà àisàn ọ̀hún.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, olùdánilẹ́kọ níbi ètò náà títún se ọ̀jọ̀gbọ́n ìmọ̀ ìsègùn òyìnbó nílẹ̀ ìwòsàn ńlá UCH, Adesọji Fasanmade sọpé wíwá ni ìlera pípé nípa sugar ara lọ́nà ọkan gbogi láti bọ́lọ́wọ́ àisàn ìtọ̀ sugar.

Àwọn tó jànfání ètò náà, tíwọ́n léè ní ọgọ́run kan, dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó sagbátẹrù ètò ọ̀hún tíwọ́n sì sọpé àisiko tódara gba lètò náà wáyé.

Kẹmi Ogunkọla/Famakin  

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *