Aare Muhammadu Buhari tí sọọ di mímọ fún olootu ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì Boris Johnson àwọn iṣẹ́ ìdàgbàsókè tó ń wáyé nílèyi, pàtàkì jùlọ labala ètò ọrọ ajé àti àgbékalè ètò náà.

Àwọn aṣáájú méjèèjì lo ṣepàdé pò níbi apejopo ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì pẹ̀lú ilẹ̀ Africa fodun 2020 èyí tó wáyé nilu London.

Ààrẹ Buhari ṣàlàyé fún Ogbeni Johnson wípé igbinyanju ifesemule ise àgbè, lọ́nà àti lè máa pèsè ànító àti aniseku iresi àtàwọn oúnjẹ onilowo min.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa Ogun gbígbé tí àwọn agbesunmomi Ààrẹ ilẹ̀ yí ṣàlàyé pé eko tí ń ṣojú mímu nípa pé àwọn aráàlú tí ń fedo lórí oronro lórí ọ̀rọ̀ ààbò.

Nínú ọ̀rọ̀ tiẹ̀, olootu ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì Boris Johnson gbosuba fún ààre Buhari wípé bo se jẹ olórí tó pegede tó sì tún gbosuba fún isejoba rẹ nípa bó ṣe lọ isẹ àgbè fún ìpèsè ise. 

Olootu ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì wá jeje ifowosowopo pẹ̀lú ilẹ̀ Nàìjíríà àtàwọn ilẹ̀ Africa tó kú lọ́nà àríwá ojútùú sí ìṣòro agbègbè Lake Chad àti igbelaruge ètò ààbò lápapò. 

Kemi Ogunkola/Rotimi Famakin

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *