Yoruba

Àwọn olóṣèlú sọ̀rọ̀ lórí ìyọnupò Sanusi

Àwọn tọrọ kàn gbongbon tí ṣàpèjúwe bí wọ́n ti ṣe ro Emir tilu Kano, Mallam Sanusi Lamido lóye gẹ́gẹ́bí èyí tí kò bá wọn lójijì.

Wọn sọ̀rọ̀ yi nínú iforowanilenuwo pẹ̀lú akoroyin ilé isẹ Radio Nàìjíríà nilu Ìbàdàn. 

Onímò nípa ọ̀rọ̀ òṣèlú kan, omowe Gbade Ojo ni àwọn ọba alaye kò si bí wón ti ṣe Lee tó kó kọjá òfin ilẹ̀ yí nítorínáà ó yẹ ki wọn maa tee jẹjẹ.

Nínú ọ̀rọ̀ tí ẹ, baálè Èkótèdó, olóyè Taye Ayorinde ni Emir tí wọ́n yọ kúrò nípò yi kò yẹ kí ó máa dásí ọ̀rọ̀ òṣèlú.

Ẹnití wón yọ lóye fúnra rẹ̀ Mallam Sanusi Lamido nínú ọ̀rọ̀ rẹ ṣàpèjúwe oun tó ṣẹlẹ̀ sii gẹ́gẹ́bí èyí tí kìí se oun tuntun lábé ọrun nítorípé ipò kii ṣe oun tó wà karinkese. 

Ówá ro àwọn alatileyin rẹ láti fàyè gba alafia, kí wọ́n sì yàgò fún jagidijagan tó lèe da omi àlàáfíà ìpínlè Kano ru.

Lilian Ibomor/Yemisi Dada 

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *