Mẹ́ta nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ alásẹ ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ni àyẹ̀wò ti fihàn wípé wọ́n ti ní àrún covid-19.

Alága ìgbìmọ̀ amúsẹ́yá lórí covid-19 nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, Gómìnà Seyi Makinde ló sísọ lójú ọ̀rọ̀ yí lórí ìkànnì abẹ́yẹfò rẹ̀.

Ó sàlàyé wípé ìjọba gba èsì àyẹ̀wò gbogbo àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ alásẹ ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ lána láàrin èyítí mẹ́ta nínú rẹ̀ fihàn pé wọ́n ti ní àrùn covid-19 nígbàtí èsì méjì nínú wọn ó yanjú.

Gómìnà Makinde wá sọ wípé wọn yíò tun àyẹ̀wò méjì tíì yanjú oun se tí wọ́n sì ti kàn sí àwọn tí wọ́n ti ní àrùn yí àti wípé wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ si ni tọpasẹ̀ àwọn tí wọ́n ti ní ìfarakínra pẹ̀lú.

Gómìnà fikún wípé tí tí ófìsì àwọn tọ́rọ kàn pa láti fín-ín tí ó wá késí àwọn ènìyàn láti máà fi àdúrà ran àwọn tí wọ́n ti ní àrùn náà lọ́wọ́ kí ara wọn báà tètè ya.

Oluwayẹmisi Dada

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *