Yoruba

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn wọ́gilé owó àyẹ̀wò COVID-19 fáwọn akẹ́kọ oníwe mẹ́wa

Ìgbaniwọlé sáwọn ilé ìwé ibití àwọn akẹ́kọ tí ńgbénú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ taládaní nípinlẹ̀ Ògùn ni yio sinmi lé ìpinu àwọn alásẹ ilé ìwé àti ẹgbẹ́ àwọn òbí àti olùkọ́.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn, ọmọba Dapọ Abiọdun ló sọ̀rọ̀ yí nígbàtí ó ńkede pé àyẹ̀wò àrùn covid-19 fún àwọn akẹ́kọ nípele ẹ̀kọ́ oníwe mẹ́wa tó ńgbé inú ilé ìwé yio jẹ́ lọ̀fẹ fún gbogbo àwọn tó wà nílé ẹ̀kọ́ t’íjọba àti t’aládani n’ípelẹ̀ náà

Nígbàtí ó ńfèsì sí ìfẹ̀hònú hàn àwọn òbí àwọn akẹ́kọ náà lórí sísan ẹgbẹ̀rún lọ́nà méèdogbọ̀n naira dandan ńdadan fún àyẹ̀wò covid-19 fún àwọn akkkọ nílé ẹ̀kọ́ aládani, Gómìnà Abiọdun ni wọ́n yíò dáwó padà fún àwọn tí wọ́n bá ti sanwó tí wọ́n sì ti wọ́gilé kíkanípá láti sàyẹ̀wò àrùn covid-19 kí wọ́n tó padà sílé ìwé.

Ó tọ́ka síì pé pẹ̀lú bí wọ́n se léè sàyẹ̀wò ẹ́ẹ̀dẹgbẹ̀ta lọ́jọ́ kan níbùdó àyẹ̀wò tí ìpínlẹ̀ náà, ó ní kò léè séèse kí wọ́n se àyẹ̀wò gbogbo wọn tán kí ìdánwò oníwe mẹ́wa tó bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ kẹtàdínlógún osù yí

Bolanle Adesida/Yẹmisi Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *