Yoruba

Ajo Ton Risi Isele Pajawiri, NEMA, Sekilo Fawon Tilewon Sunmo Eti Odo

Ajo Ton risi isele pajawiri nile yii, NEMA, ti gbawon olugbe Ipinle Osun niyanju lati kaasa won kuro ni gbogbo agbegbe ibi tomi wa tofimo eba etido lti dena fifemi ati dukia sofo.

Ajo NEMA ko sai sekilo pe awon ojo alagbara kan yoo bere sini ro laarin osu yii sosu kankanla eyi to sile yorisi isele ekun omi.

Oludari ajo naa, eka Ipinle Ekiti, Osun ati Ondo, Ogbeni Olusegun Afolayan lo soro yii dimimo lakoko ayewo sise sawon apa ibi tekun omi maa nde pelawon osise ajo naa, eka ti Ipinle Osun, OSEMA.

Ogbeni Afolayan tokasi pe Ipinle Osun wa lara awon ipinle mejidinlogbon tajo ton risi isele ayipada oju ojo nile yii, NIMET, sope o se ese kiwon foju wina isele ekun omi lodun yii.

Ko sai tun se lalaye pe ona kan gbogi lati madinku ba akoba tisele omi le ni, ni kawon eeyan faaye sile fomi kole raaye lo dada laisi idena Kankan rara.

Ololade Afonja

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *