News Yoruba

Ilé –isẹ́ àarẹ fìdí ìgbésẹ̀ àlékún tóbá owó epo múlẹ̀

Olùbádámọ̀ràn pàtàkì fún ilé-isẹ́ àarẹ tónrísọ́rọ̀ ìròyìn àti ìbáràlúsọ̀rọ̀, Mallam Garba Shehu ti sọ́ọ̀di mímọ̀ pé, ọ̀kanójókan ìpèníjà ní ilẹ̀ yíì ńbáfinra níbamu pẹ̀lú àrùn covid-19.

Àtẹ̀jáde kan tíwọ́n fisíta nílu Abuja, lèyí ti jẹyọ lákokò tón sọ̀rọ̀ lórí àlékún tó dé bá owó epo àtowó iná ọba lórílẹ̀dè yíì.

Mallam Shehu wá fìrètí hàn pé, ìtàn kòní gbàgbé àarẹ Buhari láiláì gẹ́gẹ́ bó se jẹ́ àarẹ tó gùnlẹ̀ ìgbésẹ̀ mímú àyípadà rere bá ètò ọrọ ajé fánfàní aráàlu.

Ó wá tẹnumọ ìdí tó fi sepàtàkì fáwọn èèyàn tọ́lọrun sẹ́gi ọlà fún lẹ́gbẹ́lẹ́gbẹ́ àtàwọn ẹgbẹ́, ìlọsíwájú láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìgbẹ́sẹ̀ táàrẹ ńgbé láti máyipadà rere bá ètò ọrọ ajé fánfàní gbogbo aráàlu.

Wojuade  

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *