Yoruba

Ijoba Ipinle Oyo Gule Kiko Ile Alabode L’egbeda

Gomina Ipinle Oyo, Onimo Ero Seyi Makinde ti bere eto ikole ojule toto otaleloodunrun ti owo re to billionu meji abo naira ni Ajoda lati rii wipe ileegbe toto wa fun awon omo Ipinle yi.

Eto ikole naa ti yio wa lori saree oko metala ni Ijoba Ibile Egbeda je ajumose ile ise aladani ati ijoba.

Gomina Makinde tenumo wipe o se Pataki lati pese ile gbe alaboode fun awon eniyan ilu yi npo si pelu ida meji lati odun 2018.

Gomina Makinde seleri wipe gbogbo awon eto ikole to nlo lowo nipinle yi ni won yio sagbeyewo to wa fi da awon oludokowo loju wipe won yio janfani ayika ti aabo re peye.

Saaju ninu oro re, Alaga ajo to nrisi oro ileegbe nipinle Oyo, Ogbeni Bayo Lawal tenumo ipinnu ijoba to wa lode lati mu iderun baa won eniyan nipa ipese ilegbe to dun wo.

Alakoso foro ile ati ilegbe nipinle yi, Ogbeni Abiodun Abdulraheem ro awon oludokoowo ati awon olugbe ipinle yi lati je anfani eto alailegbe yi.

Adebisi/Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *