Yoruba

Ijoba Ipinle Ogun Jeje Ilegbe Alaabode Egberun Meji Abo.

Ijoba ipinle Ogun ti ni ohun yio ko ile alaboode toto egberun meji abo fun awon olugbe ipinle Ogun laarin odun meta to nbo.

Gomina ipinle Ogun Omoba Dapo Abiodun eniti o soro yi di mimo nilu Abeokuta lasiko ayeye ojo ibugbe lagbaye ni isapa ijoba yio yanju awon ipenija aito ilegbe.

O ni ipinle naa ti nfowosowopo pelu ijoba apapo lati pese ileegbe toto egberun mewa nipinle naa lati mun adinku ba ipa ti ajakale arun covid-19 ni.

Alakoso foro ato ilu nipinle naa, Ogbeni Olayunji Odunlami ni ayeye naa yio jeki ijoba ati awon toro kan gbongbon wa ona lati mu idagbasoke baa won ilu nla nal ati awon igberiko nidi ipese ilegbe alabode fun awon eniyan.

Akori ayeye todyn yi ni “ilegbe fun gbogbo eniyan, ojo iwaju to tubo dara fun awon ilu nla” ni  o bojuwo ona lati la awon eniyan loye lori oro ilegbe ati akitiyan lati pese ile gbe alaboode fun awon eniyan jakejado agbaiye.

Oluokun/Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *