News Yoruba

Ǹkan pakọsọ láwọn apá ibìkan nílu ìbàdàn bí wọ́n tise wọ́de láti fòpin sí ikọ̀ SARS.

Ọgọọrọ àwọn ènìyàn ni wọ́n kojú ìsoro láti dé-ibití wọ́n ńlọ lóni nílu ìbàdàn lóni bí àwọn pẹ̀lú ènìyàn se wọ́de láti bèèrè fún fífòpin sí ìwà okuroro àwọn ọlọ́pa.

Akọ̀ròyìn ilé isẹ́ Radio Nàijírìa jábọ̀ wípé àwọn arìnrìnàjò ni ó ri ọ̀nà lọ tí súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ si wa tó múkí àwọn kan fẹsẹ̀rìn ọ̀nà tó jìn.

Àwọn ọ̀dọ́ náà tí wan péjọ láwọn agbègbè bíì Ìwó-Road, Gate àti lẹ́nu ìlóòro ilé isk ìjọba tó wà lágodi láti bèèrè fún fífòpin sí ikọ̀ aláàbo SARS.

Lára àwọn tó wọ́de latirí òsèré orí ìtàgé Toyin Aimaku, Adẹrin posonu Ayọ Adewọle tí àwọn ènìyàn mọ̀ sì woli àgbà àwọn tó ńta ẹ̀rọ ìbárasọ̀rọ̀, àwọn akẹ́kọ àti àwọn olósèlú.

Àwọn tó ńwọ̀de yi ni wọ́n di àwọn òpópónà tó wà nílesẹ́ ìjọba, Gate àti Ìwó-Road léyi tó múkí ǹkan pakọsọ níbẹ̀.

Diẹ lára àwọn tó bá akọ̀ròyìn ilé isẹ́ Radio Nàijírìa sọ̀rọ̀ ni fífòfin de ikọ̀ SARS nikan koto àmọ́ tí wọ́n ńbèèrè fún àtúntò ilé isẹ́ ọlọ́pa.

Nígbàtí ó ńsọ̀rọ̀ níbi ìwọ́de náà igbákejì akójanu ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, Yusuf Adebisi àti Ọlawọle Mogbọnjubọla tíì se igbékejì olórí àwọn òsìsẹ́ Gómìnà wọn rọ àwọn ọ̀dọ́ láti se súùru nítorípé Gómìnà Seyi Makinde yio sa gbogbo ipa rẹ̀ láti fòpin sí ìwà okuroro nípinlẹ̀ ọ̀yọ́.

Olurẹmi/Dada  

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *