Yoruba

Ile Ise Olopa Jeje Ilana Otun Fun Ise Won

Igbakeji oga agba Olopa lekun Guusu-Iwo Ooorun, Ogbeni Leye Oyebade ni ileese Olopa yio s’amulo ilara otun lati lee da alaafia pada sile yi.

Ogbeni Oyebade eniti o soro yi nibi ipade apero awon torokan gbongbon nilu Abeokuta ni won ti setan lati satunto ile ise Olopa lati lee jeki ise won tubo jafafa sii.

O tenumo wipe ile ise Olopa ti ngbe igbese lati ti wipe atunto naa muki ile ise olopa ile ba isesi ti won tewogba kaakiri agbaye mu.

Igbakeji Oga Agba Olopa naa fikun wipe ile ise Olopa yio tesiwaju lati sise po pelu awon ajo eleto aabo yoku lati lee ri wipe aabo  emi ati dukia tubo mu yanyan sii sile yi.

Ninu oro ro Gomina Ipinle Ogun, Omoba Dapo Abiodun eniti o ni itankale iroyin ofege je idi kan gbogi ti wahala fi be sile lasiko ifehonuhan naa, o wa gba awon omo ile yi lamonran lati maa kiyesi iroyin ti won ba nfi sori ikanni ajumolo ori ero ayelujara.

Bolanle Adesida/Oluwayemisi Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *