News

Ìjọba àpapọ̀ ńfẹ́ káwọn ọ̀dọ́ máà fàyègba ìjóko sọ̀rọ̀ pọ̀ àláfìa fún ìsọ̀kan ilẹ̀ yíì.

Alákoso fọ́rọ̀ ọ̀dọ́ àti ìdàgbàsókè eré ìdárayá nílẹ̀ yíì, ọ̀gbẹ́ni Sunday Dare, ti gbàwọn ọ̀dọ́ níyànjú láti fáàyè gba ìjóko sọ̀rọ́ àláfìa pọ̀, lọ́nà àti mú ìlọsíwájú bá orílẹ̀èdè yíì.

Ìlú Abuja lọ̀gbẹ́ni Dare ti sísọ lójú ọ̀rọ̀ yíì, níbi ètò ayẹyẹ àyájọ́ àwọn ọ̀dọ́ nílẹ̀ yíì, àkọ́kọ́ irú ẹ̀, tíwọ́n pè àkórí rẹ̀ ní ríró àwọn ọ̀dọ́ lágbára dábobo ọjọ́ iwájú ilẹ̀ yíì.

 Ó sáláyé pé, pẹ̀lú ìfẹ̀húnúhàn tó wáyé lẹ́nu lọ́ọ̀lọ́ yíì, kò lè sí àkókò tó tún dára ju àsìkò yíì lọ láti se àyájọ́ ọjọ́ àwọn ọ̀dọ́, fún kíkópa wọn sí ìdàgbàsókè ètò ọ̀rọ̀ ajé ilẹ̀ Nàijírìa.

 Gẹ́gẹ́ bálákoso náà se wípé, ànfàní ńlá gba láyájọ́ ọjọ́ àwọn ọ̀dọ́ náà jẹ́, láti filè mọ èróngbà àti ìgbésẹ̀ àwọn ọ̀dọ́ lọ́nà àti figbógúnti àwọn ìpèníjà tó ń dojùkọ wọ́n.

Ọgbẹni Dare kò sài sọ́ọ̀di mímọ̀ pé, àkòrí àyájọ́ ọjọ́ àwọn ọ̀dọ́ náà ló níse pẹ̀lú jíjẹ́kí orílẹ̀dè yíì lánfaní àti túbọ̀ náwó gọbọi lé àwọn ọ̀dọ́ ọ̀hún lórí síse ètò ìrónolágbára àti sísàwárí àwọn ẹ̀bùn tólọrun fijiki wọn.

Elizabeth Idogbe

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *