Ìgbìmọ̀ tón rírí isẹ́ ológun, nílé ìgbímọ̀ asòfin sọpé owónáà tójẹ́ billiọnu mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n naira tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún àwọn isẹ́ àkànse nílesẹ́ ológun nílẹ̀ Nàijírìa, nínú àbá ìsúná fún tọdún 2021, ni wọ́n sọpé kòtó rárá.

Alága ìgbìmọ̀ náà, Sẹnatọ Alli Ndume ló sọ̀rọ̀ yí lásìkò táwọn ọ̀gágun wá síwájú ilé, láti sọ̀rọ̀ gbe àbá ìsúná ọ̀hún.

Sẹnatọr Ndume wá pè fún kí àfikún débá owó tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún ilésẹ́ ológun nínú ètò ìsúná, tó sì tọ́kasi bétò àbò se mẹ́hẹ láwọn apá ibìkan lórílẹ̀èdè yí.

Ó fikun pé, ilésẹ́ ológun lón sisẹ́ nípinlẹ̀ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n nílẹ̀ yí, tíwọ́n sì nílò owó tótó láti lè sisẹ́ wọn bótitọ́ àti bótiyẹ papa lórí ríra àwọn on èlò ìjagun.

Jibikẹ/Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *