Ìjọba àpapọ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ìdánilẹ̀kọ fún àwọn èyàn tó wọ ẹ̀dẹ́gbẹ̀ta níye, lábẹ́ ètò ríró àwọn ọ̀dọ́ lágbára àti kíkọ́ ni nípa isẹ́ ọwọ́.

Alákoso fọ́rọ̀ agbára, ọ̀gbẹ́ni Saleh Mamman ló jẹ́ kọ́rọ̀ yí di mímọ̀ n’ípinlẹ̀ Taraba, tó sì sàpèjúwe ètò ọ̀hún gẹ́gẹ́bí èyí tón wáyé fún ríró ọ̀dọ́ lágbára nílẹ̀ Nàijírìa.

Ó tọ́kasi pé, ètò náà ni yo wójùtú sáwọn ìpèníjà tó ń mú kí ìdàgbàsókè kó fà sẹ́yìn tí yo sì mú káwọn agbègbè tí yo tiwáyé jẹ ànfàní lọ́pọ̀ nínú rẹ̀.

Alákoso sọ pé ètò ìdánilẹ́kọ yi ni yo ró àwọn ọ̀dọ́ ldẹ́gbẹ̀ta l’ágbára nínú ìpínlẹ̀ kọ̀kan nílẹ̀ yí, bẹ̀rẹ̀ láti Taraba, ó sàlàyé síwájú pé fífi orúkọ sílẹ̀ fún ètò yí, ni yo wáyé lójú òpó ayélujára lárin ọ̀sẹ̀ mẹ́ta, táwọn akópa yo lánfàní láti mú ètò ẹ̀kọ́ tí wọ́n fẹ́ yàn láàyo.

Blessing Okareh/Ọlọlade Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *